Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 “Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Ati lati igba akokò ti a o mu ẹbọ ojojumọ kuro, ati lati gbé irira isọdahoro kalẹ, yio jẹ ẹgbẹrun ati igba le ãdọrun ọjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:11
14 Iomraidhean Croise  

“Èyí ni ìwọ yóò máa fi rú ẹbọ ní orí pẹpẹ náà: Ọ̀dọ́-Àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.


“Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda fún ogójì (40) ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan.


Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá: Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ewébẹ̀ láti jẹ àti omi láti mu.


“Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀.


Yóò sọ̀rọ̀ odi sí Ọ̀gá-ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.


“Ìran alẹ́ àti ti òwúrọ̀, tí a fihàn ọ́ jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n pa ìran náà mọ́, nítorí pé, ó jẹ mọ́ ti ọjọ́ iwájú.”


Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”


Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.


“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e).


“Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ, tí a tí ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.


Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì.


Obìnrin náà sì sálọ sí aginjù, níbi tí a gbé ti pèsè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta.


A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀-òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan