Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wẹ ara wọn mọ́, tí wọn yóo sọ ara wọn di funfun, wọn yóo sì mọ́; ṣugbọn àwọn ẹni ibi yóo máa ṣe ibi; kò ní sí ẹni ibi tí òye yóo yé; ṣugbọn yóo yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ọ̀pọlọpọ li a o wẹ̀ mọ́, nwọn o si di funfun, a o si dan wọn wò: ṣugbọn awọn ẹni-buburu yio ma ṣe buburu: gbogbo awọn enia buburu kì yio kiyesi i; ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n ni yio kiyesi i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:10
37 Iomraidhean Croise  

Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.


Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.


Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.


“Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,” ni Olúwa wí. “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn, wọn ó sì funfun bí i yìnyín, bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀, wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.


Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin.


Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀.


“Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógun.


Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a ba à tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn.


Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.


Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn. Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.


Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò: wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn: èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’ àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”


Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa,


Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.


Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:


Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “ọba ni ọ́ nígbà náà?” Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”


Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi.


Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”


Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.


Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.


Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.


Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀.


Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá.


Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.


Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.


Wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.


Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun.


Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.” (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)


Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só: àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só: àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”


Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.


Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan