Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nígbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, gúúsù, ṣùgbọ́n yóò padà sí orílẹ̀-èdè Òun fúnrarẹ̀

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 On o si lọ si ijọba ọba gusu, ṣugbọn yio yipada si ilẹ ontikararẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:9
6 Iomraidhean Croise  

Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀.


“Nígbà náà ni ọba gúúsù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ-ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba gúúsù yóò borí i wọn.


“Ọba ìhà gúúsù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jù ú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá.


Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Ejibiti. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀.


Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde lọ si ìwọ̀-oòrùn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúúsù.”


Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan