Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́, èmi yóò sọ ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ. (Kò sí ẹni tí ó kún mi lọ́wọ́ fún nǹkan wọ̀nyí bí kò ṣe Mikaeli, ọmọ-aládé e yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Kò sí ẹni tí yóo gbèjà mi ninu nǹkan wọnyi àfi Mikaeli, olùṣọ́ Israẹli; Ṣugbọn n óo sọ ohun tí ó wà ninu Ìwé Òtítọ́ fún ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:21
14 Iomraidhean Croise  

Ṣùgbọ́n ọmọ-aládé ìjọba Persia dá mi dúró fún ọjọ́mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Mikaeli, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ-aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Persia.


“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà.


Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”


“Ìran alẹ́ àti ti òwúrọ̀, tí a fihàn ọ́ jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n pa ìran náà mọ́, nítorí pé, ó jẹ mọ́ ti ọjọ́ iwájú.”


Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Daniẹli, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.


“Nítorí náà, mọ èyí pé: Láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé Ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.


Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.


Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe déédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:


ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá.


Ṣùgbọ́n Mikaeli, olórí àwọn angẹli, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítorí òkú Mose, kò sọ ọ̀rọ̀-òdì sí i; Ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.”


Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mikaeli àti àwọn angẹli rẹ̀ bá dragoni náà jagun; dragoni sì jagun àti àwọn angẹli rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan