Daniẹli 10:17 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní17 Ǹjẹ́ báwo ni èmi ìránṣẹ́ ẹ̀ rẹ ṣe lè bá ọ sọ̀rọ̀, olúwa mi? Agbára mi ti lọ, agbára káká ni mo fi ń mí.” Faic an caibideilYoruba Bible17 N kò ní agbára kankan mọ́, kò sì sí èémí kankan ninu mi, báwo ni èmi iranṣẹ rẹ ti ṣe lè bá ìwọ oluwa mi sọ̀rọ̀?” Faic an caibideilBibeli Mimọ17 Nitoripé bawo ni ọmọ-ọdọ oluwa mi yi yio ti ṣe le ba oluwa mi yi sọ̀rọ? ṣugbọn bi o ṣe temi ni, lojukanna, agbara kò kù ninu mi, bẹ̃ni kò si kù ẽmi ninu mi. Faic an caibideil |
Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.” Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ: