Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:15 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Bí ó sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún mi, mo sì dorí kodò mo sì dákẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

15 Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo dojúbolẹ̀, mo sì ya odi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Nigbati o si ti sọ iru ọ̀rọ bayi fun mi tan, mo dojukọ ilẹ mo si yadi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:15
6 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì ṣí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ ààmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”


Èmi yóò mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ àjà ẹnu rẹ, tó bẹ́ẹ̀ ti ìwọ yóò wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Ìwọ kò sì ní lè bá wọn wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ní wọn


Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí ẹni tí ó sálọ náà yóò dé, ọwọ́ Olúwa sì níbẹ̀ lára mi, o sì ya ẹnu mi ki ọkùnrin náà tó wá sọ́dọ̀ mi ní òwúrọ̀. Ẹnu mí sì ṣí, èmi kò sì yadi mọ́.


Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí i, mo sùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀.


Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi.


Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan