Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:14 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Ní ìsinsin yìí mo wá láti ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú, nítorí ìran náà ń sọ nípa ọjọ́ iwájú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

14 Kí o lè mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ lẹ́yìn ọ̀la ni mo ṣe wá, nítorí ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni ìran tí o rí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Njẹ nisisiyi, mo de lati mu ọ moye ohun ti yio ba awọn enia rẹ ni ikẹhin ọjọ: nitori ti ọjọ pipọ ni iran na iṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:14
20 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Jakọbu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún un yín.


Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.


“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ìwọ rí, ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’


Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Israẹli ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gogu, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fi ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.


Ní ọdún kẹta Kirusi ọba Persia, a fi ìran kan hàn Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belteṣassari). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.


Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”


Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn.


ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:


Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gebrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”


“Ìran alẹ́ àti ti òwúrọ̀, tí a fihàn ọ́ jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n pa ìran náà mọ́, nítorí pé, ó jẹ mọ́ ti ọjọ́ iwájú.”


Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Daniẹli, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.


Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.


Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.


Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè; yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn kí yóò sìsọ èké. Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é; nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”


Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”


Àti nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú àti ìṣòro bá wá sórí i wọn, orin yìí yóò jẹ́ ẹ̀rí sí wọn, nítorí kò ní di ìgbàgbé fún àwọn ọmọ wọn. Mo mọ̀ ohun tí wọ́n ní inú dídùn sí láti ṣe, pàápàá kí èmi tó mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún wọn lórí ìbúra.”


Nítorí tí mo mọ̀ pé lẹ́yìn ikú mi, ó dájú pé ìwọ yóò padà di ìbàjẹ́ pátápátá, ẹ ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ní ọjọ́ tó ń bọ̀, ìpọ́njú yóò sọ̀kalẹ̀ sórí i yín nítorí ẹ̀yin yóò ṣe búburú níwájú Olúwa ẹ ó sì mú u bínú nípa ohun tí ọwọ́ yín ti ṣe.”


Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ Olúwa Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀.


Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé.


kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnrarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan