Daniẹli 10:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì. Faic an caibideilYoruba Bible11 Ẹni náà pè mí, ó ní, “Daniẹli, ẹni tí Ọlọrun fẹ́ràn! Dìde nàró kí o gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ, nítorí ìwọ ni a rán mi sí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo dìde nàró, ṣugbọn mo ṣì tún ń gbọ̀n. Faic an caibideilBibeli Mimọ11 O si wi fun mi pe, Danieli, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, ki oye ọ̀rọ ti mo nsọ fun ọ ki o ye ọ, ki o si duro ni ipò rẹ: nitoripe iwọ li a rán mi si nisisiyi. Nigbati on ti sọ̀rọ bayi fun mi, mo dide duro ni ìwariri. Faic an caibideil |