Daniẹli 10:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Ní ọdún kẹta Kirusi ọba Persia, a fi ìran kan hàn Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belteṣassari). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran. Faic an caibideilYoruba Bible1 Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli. Faic an caibideilBibeli Mimọ1 LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na. Faic an caibideil |