Daniẹli 1:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Ṣùgbọ́n Daniẹli pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí. Faic an caibideilYoruba Bible8 Daniẹli pinnu pé òun kò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, tabi ọtí tí ó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Nítorí náà, ó lọ bẹ Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ọba, pé kí ó gba òun láàyè kí òun má sọ ara òun di aláìmọ́. Faic an caibideilBibeli Mimọ8 Ṣugbọn Danieli pinnu rẹ̀ li ọkàn rẹ̀ pe, on kì yio fi onjẹ adidùn ọba, ati ọti-waini ti o nmu ba ara on jẹ: nitorina o bẹ̀ olori awọn iwẹfa pe, ki on má ba ba ara on jẹ. Faic an caibideil |