Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Ọba ṣètò pé kí wọn máa gbé oúnjẹ aládùn pẹlu ọtí waini fún wọn lára oúnjẹ ati ọtí waini ti òun alára. Wọn óo kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹta, lẹ́yìn náà, wọn óo máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ọba si pese onjẹ wọn ojojumọ ninu adidùn ọba ati ninu ọti-waini ti o nmu: ki a bọ wọn bẹ̃ li ọdun mẹta, pe, li opin rẹ̀, ki nwọn ki o le duro niwaju ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:5
14 Iomraidhean Croise  

Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Josẹfu nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Farao ọba Ejibiti. Josẹfu sì jáde kúrò níwájú Farao, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ejibiti


Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!


Ní ojoojúmọ́, ọba fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè.


Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ!


Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀: nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.


Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn


Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah; Nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba.


Ṣùgbọ́n Daniẹli pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí.


Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí


Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá.


Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.


Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”


Nígbà náà ni Saulu ránṣẹ́ sí Jese pé, “Jẹ́ kí Dafidi dúró níwájú mi, nítorí tí ó wù mí.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan