Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ọdún kẹta tí Jehoiakimu jẹ ọba Juda, Nebukadnessari ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kọlù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní ọdún kẹta ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, Nebukadinesari ọba Babiloni wá gbógun ti Jerusalẹmu, ó sì dótì í.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LI ọdun kẹta ijọba Jehoiakimu, ọba Juda ni Nebukadnessari, ọba Babeli, wá si Jerusalemu, o si do tì i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:1
14 Iomraidhean Croise  

Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida ọmọbìnrin Pedaiah ó wá láti Ruma.


Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Olúwa.


Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”


Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli.


Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé:


Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”


Ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé:


Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì sọ fún Baruku ọmọ Neriah ní ọdún kẹrin ti Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda. Lẹ́yìn tí Baruku ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremiah ti ń sọ:


Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu wòlíì Jeremiah láti sọ fún ará ilẹ̀ Babeli:


Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàn-dínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu.


Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì. Ní ọdún keje ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó-lé-mẹ́tàlélógún (3,023) ará Juda.


Nígbà náà ni a mú Daniẹli wá síwájú ọba, ọba sì sọ fún un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan lára àwọn tí baba mi mú ní ìgbèkùn láti Juda!


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan