Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




3 Johanu 1:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Níwájú gbogbo ìjọ níhìn-ín wọ́n jẹ́rìí sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ fún òṣìṣẹ́ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ti nwọn jẹri ifẹ rẹ niwaju ijọ: bi ìwọ bá npese fun wọn li ọna ajo wọn bi o ti yẹ nipa ti Ọlọrun, iwọ o ṣe ohun ti o dara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




3 Johanu 1:6
15 Iomraidhean Croise  

Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.”


Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”


í ẹ̀yin fàsẹ́yìn kúrò nínú ẹran ti à pa bọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti nínú àgbèrè. Bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere. Àlàáfíà.


Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.


Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà.


mo gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí Spania. Èmi yóò rí i yín ní ọ̀nà àjò mi, àti pé ẹ ó mú mi já ọ̀nà níbẹ̀ láti ọ̀dọ̀ yín lọ, lẹ́yìn tí mo bá gbádùn ẹgbẹ́ yín fún ìgbà díẹ̀.


Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea.


Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi.


Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run,


ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.


Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Senasi amòfin àti Apollo lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ohun gbogbo tí wọn nílò.


Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.


Demetriusi ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn àti ní ti òtítọ́ fúnrarẹ̀ pẹ̀lú; nítòótọ́, àwa pẹ̀lú sì gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́; ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan