Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Johanu 1:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Johanu 1:8
20 Iomraidhean Croise  

Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ.


Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!


“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn.


“Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’


Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má bá à mú yín ṣìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kristi náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.


Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀.


Àti níkẹyìn gbogbo wọn ó farahàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.


Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀.


Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó.


Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni.


Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.


Kìkì pé, ki a ma gbe ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bi èyí ti a ri gba.


Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà;


Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.


Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “gbòǹgbò ìkorò” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́.


Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán: di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan