Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 5:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nítorí náà, mo bẹ àwọn àgbà láàrin yín, alàgbà ni èmi náà, ati ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, n óo sì ní ìpín ninu ògo tí yóo farahàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 AWỌN alàgba ti mbẹ lãrin nyin ni mo bẹ̀, emi ẹniti iṣe alàgba bi ẹnyin, ati ẹlẹri ìya Kristi, ati alabapin ninu ogo ti a o fihàn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 5:1
38 Iomraidhean Croise  

Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.


Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”


Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”


Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu.


Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́.


Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.


Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí.


Jesu náà yìí ni Ọlọ́run ti jí dìde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.


Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀.


Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà.


Ní ọjọ́ kejì, a bá Paulu lọ sọ́dọ̀ Jakọbu; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀.


Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́.


Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.


Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa.


nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi,


Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bí i baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin.


Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì-mẹ́ta.


Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.


Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Krete ni pé kí o lè ṣe àṣepé àwọn iṣẹ́ tó ṣẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀.


Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi.


Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,


Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.


Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.


Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.


Nígbà tí olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá.


Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí.


Alàgbà, Sì àyànfẹ́ obìnrin ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;


Alàgbà, Sì Gaiusi, olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ nínú òtítọ́.


Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan