Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 4:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Ju ohun gbogbo lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ sí ara yín, nítorí ìfẹ́ bo ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin: nitori ifẹ ni mbò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 4:8
17 Iomraidhean Croise  

Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.


Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.


Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.


Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́, èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.


Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro.


Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga.


Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.


A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà.


Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀.


Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.


Kí ìfẹ́ ará kí o wà títí.


Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi.


Jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.


Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá.


Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan