Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Irú wọn ni Sara tí ó gbọ́ràn sí Abrahamu lẹ́nu tí ó pè é ní “Oluwa mi.” Ọmọ Sara ni yín, tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ kò jẹ́ kí nǹkankan bà yín lẹ́rù tabi kí ó mú ìpayà ba yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Gẹgẹ bi Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, ti o npè e li oluwa: ọmọbinrin ẹniti ẹnyin iṣe, bi ẹnyin ba nṣe rere, ti ohunkohun kò si dẹruba nyìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:6
12 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?”


Ẹ̀rù sì ba Sara, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rìn-ín.”


Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi nítorí òun ni olúwa rẹ kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.


“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?


Ṣùgbọ́n Peteru àti Johanu dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò.


Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan