Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Nítorí ní ìgbà àtijọ́ irú ẹwà báyìí ni àwọn aya tí a yà sọ́tọ̀, àwọn tí wọ́n ní ìrètí ninu Ọlọrun, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nitori bayi li awọn obinrin mimọ́ igbãni pẹlu, ti nwọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn li ọ̀ṣọ́, nwọn a mã tẹriba fun awọn ọkọ tiwọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:5
17 Iomraidhean Croise  

Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ


Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn


Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”


Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru.


Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.


Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi; obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe.


Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnrarẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.


bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.


Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá.


Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.


Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru.


Nípa ìgbàgbọ́ ni Sara tìkára rẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọjá ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérí sí olóòótọ́.


Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú,


Hana sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa; Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan