Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn: ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo, ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn. Ṣugbọn ojú Oluwa kan sí àwọn tí ó ń ṣe burúkú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nitori oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, etí rẹ̀ si ṣí si ẹbẹ wọn: ṣugbọn oju Oluwa nwo awọn ti nṣe buburu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:12
21 Iomraidhean Croise  

Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.


Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.


Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.


Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí.


Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.


Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”


Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.


Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà, gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.


Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan, síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.


Ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú Olúwa Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.


A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.


Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.


Èmi tìkára mi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà Moleki ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú.


Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí ní yà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún ọba Babeli, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’


Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn; ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.


“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.


“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.


“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli. “(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síhìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”


Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.


“Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojútó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan