Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 2:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́, “Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Nítorí náà, ọlá ni fún ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Ṣugbọn fún àwọn tí kò gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Òkúta tí àwọn mọlémọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki igun ilé.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nitorina fun ẹnyin ti o gbagbọ́, ọla ni: ṣugbọn fun awọn ti kò gbagbọ́, okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o di pàtaki igunle,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 2:7
26 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ́ adé tí ó lógo, àti adé tí ó lẹ́wà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.


Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.


“Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”


Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?


ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà, àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”


Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún ààmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí;


Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?


Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”


“Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà.


Ṣùgbọ́n nípa ti Israẹli ni ó wí pé, “Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”


Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Judea àti kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo ní sí Jerusalẹmu le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀,


Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?


ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.


Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ òpè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sì ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé. À ń gbé ìgbé ayé àrankàn àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórìíra ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú.


Nípa ìgbàgbọ́ ni Rahabu panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́rọ̀ nígbà tí o tẹ́wọ́gbà àwọn ààmì ní àlàáfíà.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà.


Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo;


Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye.


àti pẹ̀lú, “Òkúta ìdìgbòlù, àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.” Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan