Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 2:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe: “Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn, iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni: ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ ojú kì yóò tì í.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Nítorí ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Mo fi òkúta lélẹ̀ ní Sioni, àṣàyàn òkúta igun ilé tí ó ṣe iyebíye. Ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Nitori o mbẹ ninu iwe-mimọ́ pe, Kiyesi i, Mo fi pàtaki okuta igunle, àṣayan, iyebiye, lelẹ ni Sioni: ẹniti o ba si gbà a gbọ́ oju kì yio ti i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 2:6
27 Iomraidhean Croise  

Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu, nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli,


Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì kí wọn kí ó sì dààmú àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun: jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n, àwọn tí ń wá ìpalára mi.


Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé: “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.


Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà.


“Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà; àwọn tó ń bá ọ jà yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.


“Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀; Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.


Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí, kò tilẹ̀ jìnnà rárá; àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró. Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà ògo mi fún Israẹli.


Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́; A kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.


“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.


ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́, èmi yóò sọ ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ. (Kò sí ẹni tí ó kún mi lọ́wọ́ fún nǹkan wọ̀nyí bí kò ṣe Mikaeli, ọmọ-aládé e yín.


Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni èèkàn àgọ́ tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.


“Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn. Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi; èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí.


Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀ òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.


Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?


Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”


Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”


ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu:


Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.”


Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́


a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnrarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé;


Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo.


Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye.


àti pẹ̀lú, “Òkúta ìdìgbòlù, àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.” Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.


Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀.


Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan