Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 2:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Kí ìwà yín láàrín àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsi, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 2:12
46 Iomraidhean Croise  

Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.


Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe, kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”


Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá? Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?


Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbèrò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Daniẹli lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara.


Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dàbí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelsebulu, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!


“Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi.


Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.


Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.


“Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli; nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,


Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”


Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín, tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín, tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí ọmọ ènìyàn.


Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jesu wí pé, “Nísinsin yìí ni a yin Ọmọ ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀.


Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.


Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsin yìí.


Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.


Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ẹgbẹ́ ìlànà yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”


Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn.


Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara.


nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.


kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí, Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”


Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi àṣírí ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sin Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrín yín!”


Nítorí èyí ní ìṣògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú si jẹ́rìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ti ara ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.


Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù.


Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.


Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ìṣẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú.


Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn;


Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan;


Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.


Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè.


Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.


Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́,


Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.


Ẹ máa gbàdúrà fún wa: nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo.


Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé, “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”


Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n.


Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn.


Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi.


Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.


Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run.


Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan