Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 2:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nítorí náà, ẹ pa gbogbo ìwà ibi tì, ati ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àgàbàgebè, owú jíjẹ ati ọ̀rọ̀ àbùkù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 2:1
50 Iomraidhean Croise  

“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.


Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.


Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.


Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;


Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.


Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara, ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.


Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;


Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,


Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.


Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán,


Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”


Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:


Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.


Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.


Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.


Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un? Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.”


“Ègbé ni fún un yín, (ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisi àgàbàgebè) nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”


Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè.


Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.


Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”


Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ a fi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́.


Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankàn àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.


Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú jíjẹ, ìbínú, ìpinyà, ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, òfófó, ìgbéraga, ìrúkèrúdò, má ba à wà.


Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn:


Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.


Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo.


Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.


Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,


Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.


Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́.


Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́.


Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa?


Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.


Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.


“Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀.”


Nítorí, “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:


Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.


Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.


A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan