Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 1:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Wúrà níláti kọjá ninu iná, bẹ́ẹ̀ sì ni ó pẹ́ ni, ó yá ni, yóo ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a níláti dán igbagbọ yín tí ó ní iye lórí ju wúrà lọ wò. Irú igbagbọ bẹ́ẹ̀ yóo gba ìyìn, ògo, ati ọlá nígbà tí Jesu Kristi bá dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ki idanwò igbagbọ́ nyin, ti o ni iye lori jù wura ti iṣegbe lọ, bi o tilẹ ṣe pe iná li a fi ndán a wò, ki a le ri i fun iyìn, ati ọlá, ati ninu ogo ni igba ifarahàn Jesu Kristi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 1:7
53 Iomraidhean Croise  

Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.


Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.


Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi, ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé, ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.


Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!


Iná ni a fi fọ́ Fàdákà àti wúrà Ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.


Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.


Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere, nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un.


Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.


“Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè, ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti. Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé.


Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?


Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò: wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn: èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’ àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”


Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa,


Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.


Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá.


“Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’


“Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’


Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́.


“Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí Ọmọ ènìyàn yóò farahàn.


Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.


Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?


Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!


ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú:


Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.


Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún.


Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run.


Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò.


Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.


Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.


Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.


ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn.


Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye.


Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́, “Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”


Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín:


Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.


Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn:


Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà.


Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.


Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀.


Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀, tí o sì lè mú yín wá síwájú ògo rẹ̀ láìlábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́—


Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀; gbogbo ojú ni yóò sì rí i, àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú; àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.


Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.


Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.


Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.


“Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan