Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ọ̀nà tí a óo fi mọ Ẹ̀mí Ọlọrun nìyí: gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:2
10 Iomraidhean Croise  

Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.


Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jesu,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jesu,” bí kò ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́.


Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fihàn nínú ara, tí a dá láre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn angẹli rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.


iyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rìí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa.


Ẹnikẹ́ni tí o ba sẹ́ Ọmọ, kò gba Baba; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba jẹ́wọ́ Ọmọ, ó gba Baba pẹ̀lú.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Ọmọ Ọlọ́run ni, Ọlọ́run ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú Ọlọ́run.


Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run: èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.


Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.


Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan