Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Olùfẹ́, bí Ọlọ́run bá fẹ́ wa báyìí, ó yẹ kí a fẹ́ràn ara wa pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Olùfẹ́, bí Ọlọrun bá fẹ́ràn wa tó báyìí, ó yẹ kí àwa náà fẹ́ràn ọmọnikeji wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹràn ara wa pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:11
14 Iomraidhean Croise  

Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.” Jesu sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”


“Òfin tuntun kan ni mo fi fún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì fẹ́ràn ọmọnìkejì yín.


Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn:


Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú.


Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́.


Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa.


Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa.


Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa: nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àti gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run.


Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtètèkọ́ṣe, pé kí àwa fẹ́ràn ara wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan