Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 2:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ẹni tí ó bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ẹni tí ó bá wí pé òun wà ninu ìmọ́lẹ̀, tí ó kórìíra arakunrin rẹ̀, wà ninu òkùnkùn sibẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ẹniti o ba wipe on mbẹ ninu imọlẹ, ti o si korira arakunrin rẹ̀, o mbẹ ninu òkunkun titi fi di isisiyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 2:9
14 Iomraidhean Croise  

Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú: nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.


“Wọn kò mọ̀ ohun kankan, wọn kò lóye ohun kankan. Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn; à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.


“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.


Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́sẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran,’ nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.


Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà)


Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.


Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́.


Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkùnkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú.


Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀.


Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.


Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, “Èmi fẹ́ràn Ọlọ́run,” tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀, èké ni: nítorí ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ tí ó rí, báwo ni yóò tí ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run tí òun kò rí?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan