Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 2:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Nítorí gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìwòkúwò ojú ati afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe láti inú ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 2:16
34 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èso igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.


Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya.


“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú, èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?


Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.


Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún


Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,


Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.


Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.


Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”


Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kibirotu-Hattaafa nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúwà oúnjẹ sí.


Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrín àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fi ìtara béèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Israẹli náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí!


Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án.


Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀.


Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án.


Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.


Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si.


Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́.


Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.


Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ìṣẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú.


Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí,


Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ òpè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sì ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé. À ń gbé ìgbé ayé àrankàn àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórìíra ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú.


Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni.


Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni.


Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.”


Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́.


Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo bẹ̀ yín, bí àjèjì àti àtìpó, láti fà sẹ́hìn kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ń ba ọkàn jagun;


Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.


Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan