Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Bí a bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀ rí, a mú Ọlọrun lékèé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí ninu wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Bi awa ba wipe awa kò dẹṣẹ̀, awa mu u li eke, ọ̀rọ rẹ̀ kò si si ninu wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:10
12 Iomraidhean Croise  

“Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́, àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?


“Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké, tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”


Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tá ni ìbá dúró.


Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀ kò sì bínú sí mi.’ Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’


Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run.


Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́.


Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa.


Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n, nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètèkọ́ṣe. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ni agbára, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín, tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.


Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀.


Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ.


Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.


nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan