Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 9:8 - Bibeli Mimọ

8 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ duro na; ki emi ki o le gbọ́ aṣẹ ti OLUWA yio pa niti nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró di ìgbà tí mo bá gbọ́ àṣẹ tí OLUWA yóo pa nípa yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pàṣẹ nípa yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 9:8
19 Iomraidhean Croise  

Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin.


Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀.


Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were.


Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri ìgbala OLUWA, ti yio fihàn nyin li oni: nitori awọn ara Egipti ti ẹnyin ri li oni yi, ẹnyin ki yio si tun ri wọn mọ́ lailai.


Mose si wi fun ana rẹ̀ pe, Nitoriti awọn enia ntọ̀ mi wá lati bère lọwọ Ọlọrun ni:


Iwọ o si sọ ọ̀rọ mi fun wọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi wọn o kọ̀: nitoriti nwọn jẹ ọlọtẹ̀.


Ọmọ enia, mo ti fi iwọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli, nitorina gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, si kilọ fun wọn lati ọdọ mi wá.


Nwọn si ha a mọ́ ile-ìde, titi a o fi fi inu OLUWA hàn fun wọn.


Nwọn si há a mọ́ ile-ìde, nitoriti a kò ti isọ bi a o ti ṣe e.


Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA.


Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli?


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Nitori ọ̀rọ ti iwọ fifun mi, emi ti fifun wọn, nwọn si ti gbà a, nwọn si ti mọ̀ nitõtọ pe, lọdọ rẹ ni mo ti jade wá, nwọn si gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi.


Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi.


Nitoriti emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin.


Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara:


Nitoriti emi kò mọ̀ ohunkohun si ara mi; ṣugbọn a kò ti ipa eyi dá mi lare: Ṣugbọn ẹniti nṣe idajọ mi li Oluwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan