Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 9:5 - Bibeli Mimọ

5 Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Wọn sì ṣe é ní àṣáálẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ní aṣálẹ̀ Sinai. Àwọn eniyan náà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 9:5
18 Iomraidhean Croise  

Bẹ̃ni Noa si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ọlọrun paṣẹ fun u, bẹli o ṣe.


Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u.


Bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ṣe; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.


Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ agọ́ ti agọ́ ajọ na pari: awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA palaṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.


Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA fi aṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe gbogbo iṣẹ na.


Bayi ni awọn ọmọ Israeli si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.


Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ fun Mose.


Bayi ni Mose, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ṣe si awọn ọmọ Lefi: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe si wọn.


Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́:


Ki ẹ mã kọ́ wọn lati mã kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin.


Ọrẹ́ mi li ẹnyin iṣẹ, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin.


Nitorina, Agrippa ọba, emi kò ṣe aigbọran si iran ọ̀run na.


O si ṣe nigbati o di ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fun u li aṣẹ fun wọn;


Wò o, emi ti kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, bi OLUWA Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹnyin ki o le ma ṣe bẹ̃ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.


Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè.


Mose nitõtọ si ṣe olõtọ ninu gbogbo ile rẹ̀, bi iranṣẹ, fun ẹrí ohun ti a o sọ̀rọ wọn nigba ikẹhin;


Awọn ọmọ Israeli si dó ni Gilgali; nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla oṣù li ọjọ́ alẹ, ni pẹtẹlẹ̀ Jeriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan