Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 9:12 - Bibeli Mimọ

12 Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ẹ kò gbọdọ̀ fi àjẹkù kankan sílẹ̀ di ọjọ́ keji, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ ọ̀kankan ninu egungun ẹran tí ẹ bá fi rú ẹbọ náà. Ẹ óo ṣe ọdún Àjọ̀dún Ìrékọjá náà gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ Ìrékọjá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 9:12
7 Iomraidhean Croise  

Ẹ kò si gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rẹ̀ dé ojumọ́; eyiti o ba si kù di ijọ́ keji on ni ki ẹnyin ki o daná sun.


OLUWA si wi fun Mose ati Aaroni pe, Eyi ni ìlana irekọja: alejokalejò ki yio jẹ ninu rẹ̀:


Ni ile kan li a o jẹ ẹ; iwọ kò gbọdọ mú ninu ẹran rẹ̀ jade sode kuro ninu ile na; bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọ́ ọkan ninu egungun rẹ̀.


Nwọn o si jẹ ẹran na ti a fi iná sun li oru na, ati àkara alaiwu; ewebẹ kikorò ni nwọn o fi jẹ ẹ.


Nitoriti awọsanma OLUWA wà lori agọ́ na li ọsán, iná si wà ninu awọsanma na li oru, li oju gbogbo ile Israeli, ni gbogbo ìrin wọn.


Li ọjọ́ kẹrinla oṣù yi, li aṣalẹ, ni ki ẹnyin ki o ma ṣe e li akokò rẹ̀: gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀ gbogbo, ati gẹgẹ bi ìlana rẹ̀ gbogbo, ni ki ẹnyin ki o pa a mọ́.


Nkan wọnyi ṣe, ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, A kì yio fọ́ egungun rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan