Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:8 - Bibeli Mimọ

8 Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:8
12 Iomraidhean Croise  

EYI si li ohun ti iwọ o ṣe si wọn lati yà wọn simimọ́, lati ma ṣe alufa fun mi: mú ẹgbọ̀rọ akọmalu kan, ati àgbo meji ti kò li abùku.


Iwọ o si fi wọn sinu agbọ̀n kan, iwọ o si mú wọn wá ninu agbọ̀n na, pẹlu akọmalu na ati àgbo mejeji.


Ṣugbọn o wu Oluwa lati pa a lara; o ti fi i sinu ibanujẹ; nigbati iwọ o fi ẹmi rẹ̀ ṣẹbọ fun ẹ̀ṣẹ: yio ri iru-ọmọ rẹ̀, yio mu ọjọ rẹ̀ gùn, ifẹ Oluwa yio ṣẹ li ọwọ́ rẹ̀.


Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA.


Bayi ni ki Aaroni ki o ma wá sinu ibi mimọ́: pẹlu ẹgbọrọ akọmalu fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo fun ẹbọ sisun.


NIGBATI ẹnikan ba si nta ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ fun OLUWA, ki ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ki o jẹ ti iyẹfun daradara; ki o si dà oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀.


Nigbati ẹ̀ṣẹ ti nwọn ba ti ṣẹ̀ si i, ba di mimọ̀, nigbana ni ki ijọ enia ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá nitori ẹ̀ṣẹ na, ki nwọn ki o si mú u wá siwaju agọ́ ajọ.


Bi alufa ti a fi oróro yàn ba ṣẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ awọn enia; nigbana ni ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan alailabùku fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti ṣẹ̀.


Mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati ẹ̀wu wọnni, ati oróro itasori, ati akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo meji, ati agbọ̀n àkara alaiwu kan;


Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara:


Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan