Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:2 - Bibeli Mimọ

2 Sọ fun Aaroni, ki o si wi fun u pe, Nigbati iwọ ba tàn fitila, ki fitila mejeje na ki o ma tàn imọlẹ lori ọpá-fitila.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 kí ó sọ fún Aaroni pé, nígbà tí Aaroni bá tan fìtílà mejeeje, kí ó gbé wọn sórí ọ̀pá fìtílà kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju ọ̀pá náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Bá Aaroni sọ̀rọ̀ kí o wí fún un pé. ‘Nígbà tí ó bá ń to àwọn fìtílà, àwọn fìtílà méjèèje gbọdọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí àyíká níwájú ọ̀pá fìtílà.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:2
19 Iomraidhean Croise  

Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi.


Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe.


Iwọ o si ṣe fitila rẹ̀ na, meje: ki nwọn ki o si fi fitila wọnni sori rẹ̀, ki nwọn ki o le ma ṣe imọlẹ si iwaju rẹ̀.


O si ṣe fitila rẹ̀, meje, ati alumagaji rẹ̀, ati awo rẹ̀, kìki wurà ni.


Ọpá-fitila mimọ́, pẹlu fitila rẹ̀ wọnni, fitila ti a tò li ẹsẹ̀-ẹsẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati oróro titanna;


O si tàn fitila wọnni siwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.


Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni.


Ki o si tọju fitila lori ọpá-fitila mimọ́ nì nigbagbogbo niwaju OLUWA.


OLUWA si sọ fun Mose pẹ,


Aaroni si ṣe bẹ̃; o tàn fitila wọnni lori ọpá-fitila na, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.


Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin.


Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.


Awa si ni ọ̀rọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹ̃lọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi òkunkun, titi ilẹ yio fi mọ́, ti irawọ owurọ̀ yio si yọ li ọkàn nyin.


Mo si yipada lati wò ohùn ti mba mi sọ̀rọ. Nigbati mo yipada, mo ri ọpá fitila wura meje;


Ohun ijinlẹ ti irawọ meje na ti iwọ ri li ọwọ́ ọtún mi, ati ọpá wura fitila meje na. Irawọ meje ni awọn angẹli ìjọ meje na: ati ọpá fitila meje na ti iwọ ri ni awọn ijọ meje.


Ati lati ibi itẹ́ na ni mànamána ati ãrá ati ohùn ti jade wá: fitila iná meje si ntàn nibẹ̀ niwaju itẹ́ na, ti iṣe Ẹmi meje ti Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan