Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:16 - Bibeli Mimọ

16 Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Mo ti gbà wọ́n dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì di tèmi patapata.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:16
6 Iomraidhean Croise  

Yà gbogbo awọn akọ́bi sọ̀tọ fun mi, gbogbo eyiti iṣe akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia, ati ti ẹran: ti emi ni iṣe.


Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe:


Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.


Gbà awọn ọmọ Lefi ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi nipò ohun-ọ̀sin wọn; awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi; Emi li OLUWA.


Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u.


Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan