Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́:
Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.
Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi.