Nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na gun kẹkẹ́ titun kan, nwọn si mu u lati ile Abinadabu wá, eyi ti o wà ni Gibea: Ussa ati Ahio, awọn ọmọ Abinadabu si ndà kẹkẹ́ titun na.
Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ.