Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:13 - Bibeli Mimọ

13 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ọrẹ rẹ̀ jẹ́: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:13
23 Iomraidhean Croise  

Ati ijoko mẹwa, ati agbada mẹwa lori awọn ijoko na.


Ati ikoko, ati ọkọ́, ati awo-koto; ati gbogbo ohun-elo wọnyi ti Hiramu ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba, jẹ ti idẹ didan.


Mo si wọ̀n fàdaka ati wura fun wọn, ati ohun èlo, ani ọrẹ ti iṣe ti ile Ọlọrun wa, ti ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo Israeli ti o wà nibẹ, ta li ọrẹ:


Iwọ o si ṣe awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, ati awo rẹ̀, lati ma fi dà: kìki wurà ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn.


Eyi ni nwọn o múwa, olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, àbọ ṣekeli, ani ṣekeli ibi mimọ́: (ogún gera ni ṣekeli kan:) àbọ ṣekeli li ọrẹ fun OLUWA.


O si ṣe ohunèlo wọnni ti o wà lori tabili na, awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, lati ma fi dà ohun mimu, kìki wurà ni.


Ati awo-koto wọnni, ati ohun ifọnna wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ìkoko wọnni, ati ọpa fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati ago wọnni, eyiti iṣe ti wura, wura, ati eyiti iṣe ti fadaka, fadaka, ni balogun iṣọ kó lọ.


Bi Belṣassari ti tọ́ ọti-waini na wò, o paṣẹ pe ki nwọn ki o mu ohun-elo wura, ati ti fadaka wá, eyiti Nebukadnessari baba rẹ̀, kó jade lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu wá, ki ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, ki o le ma muti ninu wọn.


NIGBATI ẹnikan ba si nta ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ fun OLUWA, ki ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ki o jẹ ti iyẹfun daradara; ki o si dà oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀.


Ki gbogbo idiyelé rẹ ki o si jẹ́ gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: ogún gera ni ṣekeli kan.


Idiyelé rẹ fun ọkunrin yio si jẹ́ lati ẹni ogún ọdún lọ titi di ọgọta ọdún, idiyelé rẹ yio si jẹ́ ãdọta ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́.


Li ọjọ na ni MIMỌ SI OLUWA yio wà lara ṣaworo ẹṣin; ati awọn ikòko ni ile Oluwa yio si dàbi awọn ọpọ́n wọnni niwaju pẹpẹ.


Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò:


Ati idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro gigún pò.


Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.


Ani ki o gbà ṣekeli marun-marun li ori ẹni kọkan, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́ ni ki o gbà wọn; (ogun gera ni ṣekeli kan):


Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.


Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;


Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;


A si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, a si fifun ọmọbinrin na; o si gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ.


Ẹniti iya rẹ̀ ti kọ́ tẹlẹ ri, o wipe, Fun mi li ori Johanu Baptisti nihinyi ninu awopọkọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan