Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:12 - Bibeli Mimọ

12 Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ní ọjọ́ kinni, Naṣoni ọmọ Aminadabu, olórí ẹ̀yà Juda mú ẹbọ tirẹ̀ wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ní Nahiṣoni ọmọ Amminadabu láti inú ẹ̀yà Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:12
13 Iomraidhean Croise  

O si ṣe nigbati Israeli joko ni ilẹ na, Reubeni si wọle tọ̀ Bilha, àle baba rẹ̀ lọ; Israeli si gbọ́. Njẹ awọn ọmọ Jakobu jẹ́ mejila.


Awọn ọmọ Lea; Reubẹni, akọ́bi Jakobu, ati Simeoni, ati Lefi, ati Judah, ati Issakari, ati Sebuluni.


Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.


Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ.


Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri.


Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu.


Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu.


Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda.


OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ.


Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;


Aramu si bí Aminadabu; Aminadabu si bí Naaṣoni; Naaṣoni si bí Salmoni;


Ti iṣe ọmọ Jesse, ti iṣe ọmọ Obedi, ti iṣe ọmọ Boasi, ti iṣe ọmọ Salmoni, ti iṣe ọmọ Naassoni,


Amminadabu si bi Naṣoni, Naṣoni si bi Salmoni;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan