Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:11 - Bibeli Mimọ

11 OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 OLUWA sọ fún Mose pé, “Kí olukuluku olórí mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ wá ní ọjọ́ tirẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nítorí tí Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:11
5 Iomraidhean Croise  

Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na.


Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.


Nitori Ọlọrun kì iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ́.


Ẹ mã ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ.


Nitoripe bi emi kò tilẹ si lọdọ nyin li ara, ṣugbọn emi mbẹ lọdọ nyin li ẹmí, mo nyọ̀, mo si nkiyesi eto nyin, ati iduroṣinṣin igbagbọ́ nyin ninu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan