Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:10 - Bibeli Mimọ

10 Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá síwájú pẹpẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:10
12 Iomraidhean Croise  

Solomoni si ru ẹbọ ọrẹ-alafia, ti o ru si Oluwa, ẹgbã-mọkanla malu, ati ọkẹ mẹfa àgutan. Bẹ̃ni ọba ati gbogbo awọn ọmọ Israeli yà ile Oluwa si mimọ́.


Solomoni ọba si rubọ ẹgbã-mọkanla malu ati ọkẹ mẹfa agutan: bẹ̃ni ọba, ati gbogbo awọn enia yà ile Ọlọrun na si mimọ́.


Ati li ọjọ kẹjọ nwọn ṣe apejọ mimọ́; nitori ti nwọn ṣe ìyasi-mimọ́ pẹpẹ na li ọjọ meje, ati àse na, ọjọ meje.


Ati nigba yiya odi Jerusalemu si mimọ́, nwọn wá awọn ọmọ Lefi kiri ninu gbogbo ibugbe wọn, lati mu wọn wá si Jerusalemu lati fi ayọ̀ ṣe iyà si mimọ́ na pẹlu idupẹ ati orin, pẹlu simbali, psalteri, ati pẹlu dùru.


Li ọjọ na pẹlu nwọn ṣe irubọ nla, nwọn si yọ̀ nitori Ọlọrun ti mu wọn yọ̀ ayọ̀ nla, aya wọn ati awọn ọmọde yọ̀ pẹlu, tobẹ̃ ti a si gbọ́ ayọ̀ Jerusalemu li okere reré.


EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi.


OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́;


OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ.


Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, li ọjọ́ ti a ta oróro si i, lati ọwọ́ awọn olori Israeli wá: awopọkọ fadakà mejila, awokòto fadakà mejila, ṣibi wurà mejila:


Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i.


Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia, pe, Ọkunrin wo li o kọ ile titun, ti kò ti ikó si i? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba kó si i.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan