Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:9 - Bibeli Mimọ

9 Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 “Bí ẹnìkan bá kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lójijì, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ orí rẹ̀ di aláìmọ́; yóo dúró fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje tí í ṣe ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, yóo fá irun orí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 “ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:9
11 Iomraidhean Croise  

Ati li ọjọ ti yio lọ si ibi-mimọ́, si agbalá ti inu, lati ṣe iranṣẹ ni ibi-mimọ́, on o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi.


Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje.


Yio si ṣe ni ijọ́ keje, ni ki o fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro li ori rẹ̀, ati irungbọn rẹ̀, ati ipenpeju rẹ̀, ani gbogbo irun rẹ̀ ni ki o fá kuro: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ pẹlu ninu omi, on o si di mimọ́.


Ki Nasiri na ki o fá ori ìyasapakan rẹ̀ li ẹnu-ọ̀na agọ́ àjọ, ki o si mú irun ori ìyasapakan rẹ̀ ki o si fi i sinu iná ti mbẹ labẹ ẹbọ alafia na.


Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀, mimọ́ li on fun OLUWA.


Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ.


Nigbati ọjọ meje si fẹrẹ pé, ti awọn Ju ti o ti Asia wa ri i ni tẹmpili, nwọn rú gbogbo awọn enia soke, nwọn nawọ́ mu u.


Nigbana ni ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ; ki on ki o si fá ori rẹ̀, ki o si rẹ́ ẽkanna rẹ̀;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan