Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:5 - Bibeli Mimọ

5 Ni gbogbo ọjọ́ ileri ìyasapakan rẹ̀, ki abẹ kan máṣe kàn a li ori: titi ọjọ́ wọnni yio fi pé, ninu eyiti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, ki o jẹ́ mimọ́, ki o si jẹ ki ìdi irun ori rẹ̀ ki o ma dàgba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 “Kò gbọdọ̀ gé irun orí rẹ̀ tabi kí ó fá a títí tí ọjọ́ tí ó fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo fi pé, kí ó jẹ́ mímọ́, kí ó sì jẹ́ kí ìdì irun orí rẹ̀ máa dàgbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:5
9 Iomraidhean Croise  

Nwọn kì o si fá ori wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio jẹ ki irun wọn gbọ̀; ni rirẹ nwọn o rẹ irun ori wọn.


Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ni ki o gbọdọ jẹ ohun kan ti a fi eso-àjara ṣe, lati kóro rẹ̀ titi dé ẽpo rẹ̀.


Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ.


Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini.


Li on si sọ gbogbo eyiti o wà li ọkàn rẹ̀ fun u, o si wi fun u pe, Abẹ kò kàn ori mi rí; nitoripe Nasiri Ọlọrun li emi iṣe lati inu iya mi wá: bi a ba fá ori mi, nigbana li agbara mi yio lọ kuro lọdọ mi, emi o si di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.


O si mú ki o sùn li ẽkun rẹ̀; o si pè ọkunrin kan, o si mu ki o fá ìdi irun mejeje ori rẹ̀; on si bẹ̀rẹsi pọ́n ọ loju, agbara rẹ̀ si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.


On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan