Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:12 - Bibeli Mimọ

12 Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Lẹ́yìn náà ni ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a kì yóo ka àwọn ọjọ́ tí ó ti lò ṣáájú nítorí pé ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti bàjẹ́ nítorí pé ó fi ara kan òkú. Yóo sì mú ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan tọ alufaa wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:12
12 Iomraidhean Croise  

Ailabùku ni ki ọdọ-agutan nyin ki o jẹ́, akọ ọlọdún kan: ẹnyin o mú u ninu agutan, tabi ninu ewurẹ:


Ṣugbọn nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedede, ti o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo irira ti enia buburu nṣe, on o ha yè? gbogbo ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni a kì yio ranti: ninu irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ninu wọn ni yio kú.


Ki alufa ki o si mú ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.


Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.


Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun.


Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun, ki o si ṣètutu fun u, nitoriti o ṣẹ̀ nipa okú, ki o si yà ori rẹ̀ simimọ́ li ọjọ́ na.


Eyi si li ofin ti Nasiri, nigbati ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ba pé: ki a si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:


Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà.


Jesu si dahùn, o wi fun u pe, Jọwọ rẹ̀ bẹ̃ na: nitori bẹ̃li o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀.


Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ́, ti o si rú ọ̀kan, o jẹbi gbogbo rẹ̀.


Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan