Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:9 - Bibeli Mimọ

9 Ati gbogbo ẹbọ agbesọsoke ohun mimọ́ gbogbo ti awọn ọmọ Israeli, ti nwọn mú tọ̀ alufa wá, yio jẹ́ tirẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Àwọn alufaa ni wọ́n ni gbogbo àwọn ohun ìrúbọ, ati gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá sọ́dọ̀ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:9
19 Iomraidhean Croise  

Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA.


Ki ẹnyin ki o si jẹ ẹ ni ibi mimọ́, nitoripe ipín tirẹ, ati ipín awọn ọmọ rẹ ni, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: nitoripe, bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi.


Ati igẹ̀ fifì, ati itan agbesọsoke ni ki ẹnyin ki o jẹ ni ibi mimọ́ kan; iwọ, ati awọn ọmọkunrin rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ pẹlu rẹ: nitoripe ipín tirẹ ni, ati ipín awọn ọmọ rẹ, ti a fi fun nyin ninu ẹbọ alafia awọn ọmọ Israeli.


Itan agbesọsoke ati igẹ̀ fifì ni ki nwọn ki o ma múwa pẹlu ẹbọ ti a fi iná ṣe ti ọrá, lati fì i fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA: yio si ma jẹ́ tirẹ, ati ti awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nipa ìlana titilai; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ.


Alufa ti o ru u fun ẹ̀ṣẹ ni ki o jẹ ẹ: ni ibi mimọ́ kan ni ki a jẹ ẹ, ninu agbalá agọ́ ajọ.


Itan ọtún ni ki ẹnyin ki o fi fun alufa, fun ẹbọ agbesọsoke ninu ẹbọ alafia nyin.


Nitoripe igẹ̀ fifì ati itan agbeṣọsoke, ni mo gbà lọwọ awọn ọmọ Israeli ninu ẹbọ alafia wọn, mo si fi wọn fun Aaroni alufa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa ìlana titilai, lati inu awọn ọmọ Israeli.


Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ.


Mose si fi idá ti ẹbọ igbesọsoke OLUWA fun Eleasari alufa, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.


Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u.


Kìki ohun mimọ́ rẹ ti iwọ ní, ati ẹjẹ́ rẹ ni ki iwọ ki o mú, ki o si lọ si ibi ti OLUWA yio yàn:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan