Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:8 - Bibeli Mimọ

8 Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Ṣugbọn bí ẹni tí ó ṣẹ̀ náà bá ti kú, tí kò sì ní ìbátan tí ó lè gba owó ìtanràn náà, kí ó san owó náà fún àwọn alufaa OLUWA. Lẹ́yìn èyí ni yóo mú àgbò wá fún ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:8
8 Iomraidhean Croise  

Owo ẹbọ irekọja ati owo ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni a kò mu wá sinu ile Oluwa: ti awọn alufa ni.


Ki o si ṣe atunṣe nitori ibi ti o ti ṣe ninu ohun mimọ́, ki o si fi idamarun pẹlu rẹ̀, ki o si fi i fun alufa: alufa yio si fi àgbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.


Tabi gbogbo eyi na nipa eyiti o bura eké; ki o tilẹ mú u pada li oju-owo rẹ̀, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si fi i fun olohun, li ọjọ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀.


Bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ si li ẹbọ ẹbi: ofin kan ni fun wọn: alufa ti nfi i ṣètutu ni ki on ní i.


Nigbana ni ki nwọn ki o jẹwọ ẹ̀ṣẹ ti nwọn ṣẹ̀: ki o si san ẹsan ẹ̀ṣẹ rẹ̀ li oju-owo, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun ẹniti on jẹbi rẹ̀.


Ati gbogbo ẹbọ agbesọsoke ohun mimọ́ gbogbo ti awọn ọmọ Israeli, ti nwọn mú tọ̀ alufa wá, yio jẹ́ tirẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan