Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:3 - Bibeli Mimọ

3 Ati ọkunrin ati obinrin ni ki ẹnyin ki o yọ kuro, lẹhin ode ibudó ni ki ẹ fi wọn si; ki nwọn ki o máṣe sọ ibudó wọn di alaimọ́, lãrin eyiti Emi ngbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ẹ kó wọn sí ẹ̀yìn odi kí wọn má baà sọ ibùdó yín di aláìmọ́ nítorí pé mò ń gbé inú rẹ̀ pẹlu àwọn eniyan mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:3
23 Iomraidhean Croise  

A si fi igi kedari tẹ́ ẹ loke lori iyara ti o joko lori ọwọ̀n marunlelogoji, mẹdogun ni ọ̀wọ́.


Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe.


Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn.


Emi o si ma gbé ãrin awọn ọmọ Israeli, emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.


Kigbe, si hó, iwọ olugbe Sioni: nitori ẹni titobi ni Ẹni-Mimọ́ Israeli li ãrin rẹ.


Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje.


Bayi ni ki ẹnyin ki o yà awọn ọmọ Israeli kuro ninu aimọ́ wọn; ki nwọn ki o má ba kú ninu aimọ́ wọn, nigbati nwọn ba sọ ibugbé mi ti mbẹ lãrin wọn di aimọ́.


Nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, nwọn si wi fun wọn pe, O tó gẹ, nitoripe gbogbo ijọ li o jẹ́ mimọ́, olukuluku wọn, OLUWA si mbẹ lãrin wọn: nitori kili ẹnyin ha ṣe ngbé ara nyin ga jù ijọ OLUWA lọ?


Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Iwọ kò si gbọdọ sọ ilẹ na di alaimọ́, ninu eyiti ẹnyin o joko, ninu eyiti emi ngbé: nitori Emi JEHOFA ni ngbé inu awọn ọmọ Israeli.


Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si yọ wọn sẹhin ibudó: bi OLUWA ti sọ fun Mose, bẹ̃ li awọn ọmọ Israeli ṣe.


Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ nrìn lãrin ibudó rẹ, lati gbà ọ, ati lati fi awọn ọtá rẹ fun ọ; nitorina ki ibudó rẹ ki o jẹ́ mimọ́: ki on ki o máṣe ri ohun aimọ́ kan lọdọ rẹ, on a si pada lẹhin rẹ.


Iwọ kò gbọdọ fà ẹrú ti o sá lati ọdọ oluwa rẹ̀ tọ̀ ọ wá lé oluwa rẹ̀ lọwọ:


Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ìlana ti nwọn ti gbà lọwọ wa.


Ẹniti o ba ṣe aladamọ̀ lẹhin ìkilọ ikini ati ekeji, kọ̀ ọ;


Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.


Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan