Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:21 - Bibeli Mimọ

21 Nigbana ni ki alufa ki o mu ki obinrin na fi èpe bura, ki alufa ki o si wi fun obinrin na pe, Ki OLUWA ki o sọ ọ di ẹni egún, ati ẹni ifire ninu awọn enia rẹ, nigbati OLUWA ba mu itan rẹ rà, ti o si mu inu rẹ wú;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 kí OLUWA sọ ọ́ di ẹni ègún ati ẹni ìfibú láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Kí OLUWA mú kí abẹ́ rẹ rà, kí ó sì mú kí ara rẹ wú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrín àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ̀ sì wú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:21
9 Iomraidhean Croise  

Iwọ o ṣe aisan pupọ, àrun nla ninu ifun rẹ, titi ifun rẹ yio fi tu jade nitori àrun ọjọ pupọ.


Nwọn faramọ awọn arakunrin wọn, awọn ijoye wọn, nwọn si wọ inu èpe ati ibura, lati ma rìn ninu ofin Ọlọrun, ti a fi lelẹ nipa ọwọ Mose iranṣẹ Ọlọrun, lati kiyesi, ati lati ṣe gbogbo aṣẹ Jehofah, Oluwa wa, ati idajọ rẹ̀, ati ilana rẹ̀;


Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà.


Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran:


Ati lati ọdọ wọn li a o da ọ̀rọ-egún kan silẹ li ẹnu gbogbo igbekun Juda ti o wà ni Babeli, wipe; Ki Oluwa ki o ṣe ọ bi Sedekiah, ati bi Ahabu, awọn ẹniti ọba Babeli sun ninu iná.


Nigbati o ba si mu omi na tán, yio si ṣe, bi o ba ṣe ẹni ibàjẹ́, ti o si ṣẹ̀ ọkọ rẹ̀, omi ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò, inu rẹ̀, a si wú, itan rẹ̀ a si rà: obinrin na a si di ẹni egún lãrin awọn enia rẹ̀.


Nigbana li o bẹ̀rẹ si ibura ati si iré, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na. Lojukanna akukọ si kọ.


Joṣua si gégun li akokò na wipe, Egún ni fun ọkunrin na niwaju OLUWA ti yio dide, ti yio si kọ ilu Jeriko yi: pẹlu ikú akọ́bi rẹ̀ ni yio fi pilẹ rẹ̀, ati pẹlu ikú abikẹhin rẹ̀ ni yio fi gbé ilẹkun ibode rẹ̀ ró.


Awọn ọkunrin Israeli si ri ipọnju gidigidi ni ijọ na: nitoriti Saulu fi awọn enia na bu pe, Ifibu ni fun ẹniti o jẹ onjẹ titi di alẹ titi emi o si fi gbẹsan lara awọn ọta mi. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu awọn enia na ti o fi ẹnu kan onjẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan