Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:2 - Bibeli Mimọ

2 Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o yọ gbogbo adẹ̀tẹ kuro ni ibudó, ati gbogbo ẹniti o ní isun, ati ẹnikẹni ti o di alaimọ́ nipa okú:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n lé gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ kúrò ní ibùdó wọn, gbogbo àwọn tí ó ni ọyún lára ati ẹnikẹ́ni tí ó di aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:2
15 Iomraidhean Croise  

Adẹtẹ̀ mẹrin kan si wà ni atiwọ̀ bodè; nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú?


Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́.


Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.


Alufa yio wò o, kiyesi i, apá na ràn li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ẹ̀tẹ ni.


Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje.


OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu awọn enia rẹ̀ kò gbọdọ di alaimọ́ nitori okú.


Nitoripe ọkànkọkàn ti kò ba pọ́n ara rẹ̀ loju li ọjọ́ na yi, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.


Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ.


OLUWA si wi fun Mose pe, Bi baba rẹ̀, tilẹ tu itọ si i li oju, njẹ oju ki ba tì i ni ijọ́ meje? Ki a sé e mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje, lẹhin eyinì ki a gbà a sinu rẹ̀.


Ki ẹnyin ki o si duro lẹhin ibudó ni ijọ meje: ẹnikẹni ti o ba pa enia, ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ẹniti a pa, ki ẹnyin si wẹ̀ ara nyin mọ́, ati ara awọn igbẹsin nyin ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan