OLUWA si wi fun Mose pe, Bi baba rẹ̀, tilẹ tu itọ si i li oju, njẹ oju ki ba tì i ni ijọ́ meje? Ki a sé e mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje, lẹhin eyinì ki a gbà a sinu rẹ̀.
Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA li a kà wọn nipa ọwọ́ Mose, olukuluku nipa iṣẹ-ìsin rẹ̀, ati gẹgẹ bi ẹrù rẹ̀: bẹ̃li a ti ọwọ́ rẹ̀ kà wọn, bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.